13. “ ‘Èmi yóò kúkú pàtẹ́wọ́ lórí èrè àìmọ̀ tí ìwọ ti jẹ, àti lórí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀ ní àárin yín.
14. Ǹjẹ́ ìwọ yóò lè ní ìgboyà tó, tàbí ọwọ́ rẹ yóò ni agbára ní ọjọ́ tí èmi yóò ni ṣíṣe pẹ̀lú rẹ? Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, Èmi yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀.
15. Èmi yóò tú kán ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò fọ́n ọ ká sí àwọn ìlú; èmi yóò sì fi òpin sí àìmọ́ rẹ.
16. Nígbà tí a ó bà ọ́ jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀ èdè, ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”
17. Nígbà náà ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
18. “Ọmọ ènìyàn, ilé Ísírẹ́lì ti di ìdárọ́ sí mi; gbogbo wọn jẹ́ bàbà, tánúnganran, ìrin àti òjé ti a fi sínú iná ìléru. Wọn jẹ́ ìdàrọ́ ti fàdákà.
19. Nítorí náà èyí yìí ni ohun ti Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Nítorí tí ìwọ ti di ìdárọ́, èmi yóò kó yín jọ sí Jérúsálẹ́mù.