Ísíkẹ́lì 16:45-53 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

45. Ọmọ ìyà rẹ ni ọ lóòtọ́, to korìíra ọkọ rẹ àti àwọn ọmọ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ara ilé àwọn arábìnrin rẹ ni ọ nitootọ, àwọn to n korìíra ọkọ wọn sílẹ̀, tó tún ń korìíra àwọn ọmọ. Ará Híítì ni ìyá rẹ, baba rẹ si jẹ́ ara Ámórì.

46. Ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin ni Samaríà, òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ n gbé ni apá aríwá rẹ, Sódómù sì ni àbúrò rẹ, obìnrin tó ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ ni ìhà gúúsù rẹ.

47. Kì í sẹ pé ìwọ rìn ni ọ̀nà wọn nìkan, tàbí ṣe àfiwé ìwà irira wọn ṣùgbọ́n ní àárin àkókò kúkúrú díẹ̀, ìwọ bàjẹ́ jù wọ́n lọ

48. Olúwa Ọlọ́run wí pé, Bí mo ṣe wà láàyè Sódómù tí í se ẹgbọ́n rẹ obìnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ kò ṣe to ohun tí ìwọ àti ọmọbìnrin rẹ ṣe.

49. “ ‘Wò ó, ẹ̀sẹ̀ tí Sódómù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin sẹ̀ nìyìí: Òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ gbéraga, wọ́n jẹ́ alájẹjù àti aláìbìkítà; wọn kò ran talákà àti aláìní lọ́wọ́

50. Nítorí náà, mo mu wọn kúrò níwájú mi lójú mi gẹ́gẹ́ bi iwọ ti ròó, nítorí ìgbéraga àti àwọn Ohun ìríra tí wọ́n ṣe.

51. Samaríà kò ṣe ìdájìn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Ìwọ ṣe àwọn ohun ìríra ju tirẹ̀ lọ, ìwọ sì jẹ kí àwọn arabìnrin rẹ dàbí olódodo pẹ̀lú gbogbo ìwọ̀nyí tí ìwọ ti ṣe.

52. Gba ìtìjú rẹ, nítorí ìwọ ti jẹ́ kí arábìnrin rẹ gba ìdáláre. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ti burú ju tí wọn lọ, wọn dàbí olódodo ju ìwọ lọ. Torí náà rú ìtíjú rẹ, kí o sì gba ẹ̀gàn rẹ pẹ̀lú nítorí ìwọ ti jẹ́ kí àwọn arábìnrin rẹ dàbí olódodo.

53. “ ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sódómù àti àwọn ọmọbìnrin rẹ padà ìgbèkùn àti Samaríà pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ, èmi yóò sì dá ìgbèkùn tirẹ̀ náà padà pẹ̀lú wọn

Ísíkẹ́lì 16