Ìṣe Àwọn Àpósítélì 8:31-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Ó sì dáhùn wí pé, “Yóò ha ṣe yé mi, bí kò ṣe pé ẹnìkan tọ́ mí sí ọ̀nà?” Ó sì bẹ Fílípì kí ó gòkè wá, kí ó sì bá òun jókòó.

32. Ibi-ìwé-mímọ́ tí Ìwẹ̀fà náà ń kà náà ni èyí:“A fà á bí àgùntàn lọ fún pípa;àti bí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń dákẹ́ níwájú olúrẹ́run rẹ̀,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kò wí ohun kan.

33. Nínú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ a fi ìdájọ́-ododo dùn ún:Ta ni ó le sọ̀rọ̀ nípa ti àwọn ìran rẹ̀?Nítorí tí a gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò ní ayé.”

34. Ìwẹ̀fà náà sì sọ fún Fílípì pé, “Mo bẹ̀ ọ́ sọ fún mi, nípa ta ni wòlíì náà ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nípa ara rẹ̀ tàbí nípa ẹlòmìíràn?”

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 8