Ìṣe Àwọn Àpósítélì 5:16-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú tí ó yí Jerúsálémù ká, wọn ń mú àwọn abirùn wá àti àwọn tí ara kan fún ẹ̀mí àìmọ́; a sì mu olúkúlùkù wọn ní ara dá.

17. Nígbà náà ni ẹ̀mí owú gbígbóná gbé olórí àlúfáà àti gbogbo àwọn tí wọn wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ì ṣe ẹ̀yà tí àwọn Sádúsì wọ̀.

18. Wọ́n sì nawọ́ mú àwọn àpósítélì wọn sì fi wọ́n sínú túbú.

19. Ṣùgbọ́n ní òru, áńgẹ́lì Olúwa ṣí ìlẹ̀kùn túbú; ó sì mú wọn jáde.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 5