29. Pọ́ọ̀lù sì dáhùn wí pé, “Ní àkókò kúkúrú tàbí gígùn: mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó má ṣe ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí pẹ̀lú lè di irú ènìyàn tí èmi jẹ́ láìsí ẹ̀wọ̀n wọ̀nyí.”
30. Nígbà tí ó sì sọ nǹkan wọ̀nyí tan, ọba dìde, àti baálẹ̀, àti Béníkè, àti àwọn tí o bá wọn jokòó;
31. Nígbà tí wọn wọ yẹ̀wù lọ, wọn bá ara wọn jíròrò, wọ́n sọ pé, “Ọkùnrin yìí kò ṣe nǹkan kan tí ó yẹ sí ikú tàbí sì ẹ̀wọ̀n.”
32. Àgírípà sì wí fún Fẹ́sítúsì pé, “A bà dá ọkùnrin yìí ṣílẹ̀ bí ó bá ṣe pè kòì tíì fi ọ̀ràn rẹ̀ lọ Késárì.”