Ìṣe Àwọn Àpósítélì 21:38-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

38. Ìwọ ha kọ ní ara Íjíbítì náà, tí ó ṣọ̀tẹ̀ ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, ti ó sì ti mú ẹgbàajì ọkùnrin nínú àwọn tí í ṣe apànìyàn lẹ́yìn lọ ṣí ijù?”

39. Ṣùgbọ̀n Pọ́ọ̀lù sì wí pé, “Júù ní èmi jẹ́, ará Tásọ́sì ilú Kílíkíà, tí kì í ṣe ìlú yẹpẹrẹ kan, èmi ṣí bẹ̀ ọ, fún mi ní ààyè láti bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí sọ̀rọ̀!”

40. Nígbà tí ó sì tí fún un ní ààyè, Pọ́ọ̀lù dúró lórí àtẹ̀gùn, ó sì juwọ́ sí àwọn ènìyàn. Nígbà tí wọ́n sì dákẹ́rọ́rọ́, ó bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù, wí pé:

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 21