Ìṣe Àwọn Àpósítélì 17:29-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. “Ǹjẹ́ bí àwa bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, kò yẹ fún wa láti rò pé, Ẹni-Ijọ́sìn-sí wa dàbí wúrà, tàbí fàdákà, tàbí òkúta, tí a fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ ènìyàn ya èré àwòrán rẹ̀.

30. Pẹ̀lúpẹ̀lù ìgbà àìmọ̀ yìí ni Ọlọ́run tí gbójú fò dá; ṣùgbọ́n nísìnyìí ó pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti ronúpìwàdà;

31. Níwọ̀n bí ó ti dá ọjọ́ kan, nínú èyí tí yóò ṣe ìdájọ́ ayé lódodo nípaṣẹ̀ ọkùnrin náà tí ó ti yàn, nígbà tí ó ti fi ohun ìdánilójú fún gbogbo ènìyàn, níti pé ó jí dìde kúrò nínú òkú.”

32. Nígbà tí wọ́n ti gbọ́ ti àjíǹde òkú, àwọn mìíràn ń ṣẹ̀fẹ̀: ṣùgbọ́n àwọn mìíràn wí pé, “Àwa o tún nǹkan yìí gbọ́ lẹ́nu rẹ̀.”

33. Bẹ́ẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù sì jáde kúrò láàrin wọn.

34. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin kan fi ara mọ́ ọn, wọ́n sì gbàgbọ́: nínú àwọn ẹni tí Díónísíù ara Aréópágù wà, àti obìnrin kan tí a ń pè ni Dámárì, àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 17