Ìṣe Àwọn Àpósítélì 12:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Àwọn ènìyàn sì hó wí pé, “Ohùn ọlọ́run ni, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!”

23. Lójúkan náà, nítorí ti Hẹ́rọ́dù kò fi ògo fún Ọlọ́run, ańgẹ́lì Olúwa lù ú, ó sì kú, ìdin sì jẹ ẹ́.

24. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbilẹ̀, ó sì bí sí i.

25. Bánábà àti Ṣọ́ọ̀lù sì padà wá láti Jerúsálémù, nígbà ti wọ́n sì parí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn, wọn sì mú Jòhánù ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Máàkù wá pẹ̀lú wọn.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 12