10. Mo sọ fún àwọn wòlíì,mo fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìran hàn wọ́nmo sì pa òwe láti ẹnu wòlíì wọn.”
11. Gílíádì ha burú bí?Àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ asán.Ǹjẹ́ wọ́n ń fi akọ màlúù rúbọ ní Gílígálì?Gbogbo pẹpẹ wọ́n sì dàbí ebènínú aporo oko.
12. Jákọ́bù sá lọ si orílẹ̀ èdè Árámù;Ísírẹ́lì sìn kí o tó fẹ ìyàwóó ṣe ìtọjú ẹran láti fi san owó ìyàwó.
13. Olúwa lo wòlíì kan láti mú Ísírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì,nípaṣẹ̀ wòlíì kan ó ṣe ìtọ́jú rẹ̀.