Gálátíà 4:10-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ẹ̀yin ń kíyèsí ọjọ́ àti àkókò, àti ọdún.

11. Ẹ̀rù yin ń bà mí, kí o má bà ṣe pé lásán ni mo ṣe làálàá lórí yín.

12. Ará, mo bẹ̀ yín, ẹ dà bí èmi: nítorí èmi dà bí ẹ̀yin: èyin kò ṣe mí ní ibi kan.

13. Ẹ̀yin mọ̀ pé nínú àìlera ni mo wàásù ìhìnrere fún yín ní àkọ́kọ́.

14. Èyí tí ó sì jẹ́ ìdánwò fún yín ní ara mi ni ẹ kò kẹ́gàn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì kọ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gbà mí bí áńgẹ́lì Ọlọ́run, àní bí Kírísítì Jésù.

Gálátíà 4