Gálátíà 3:21-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Nítorí náà òfín ha lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọ́run bí? Kí a má rí i; Nítorí ìbá ṣe pé a ti fi òfin kan fún ni tí ó lágbára láti sọni di ààyè nítòótọ́ òdodo ìbá ti tipasẹ̀ òfin wà.

22. Ṣùgbọ́n ìwé-mímọ́ ti sé gbogbo nǹkan mọ́ sábẹ́ ẹṣẹ̀, kí a lè fi ìlérí nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì fún àwọn tí ó gbàgbọ́.

23. Ṣùgbọ́n kí ìgbàgbọ́ tó dé, a ti pa wá mọ́ lábẹ́ òfin, a sì sé wa mọ́ de ìgbàgbọ́ tí a ń bọ̀ wá fi hàn.

24. Nítorí náà òfin ti jẹ́ olùkọ́ni láti múni wá sọ́dọ̀ Kírísítì, kí a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́.

25. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí ìgbàgbọ́ ti dé, àwa kò sí lábẹ́ olùkọ́ni mọ́.

Gálátíà 3