1. Ẹ̀yin aláìnírònú ará Gálátíà! ta ní ha tàn yín jẹ, kí ẹ̀yin má ṣe gba òtítọ́ gbọ́? Ní ojú ẹni tí a fi Jésù Kírísítì hàn gbangba láàrin yín ni ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú.
2. Kìkì èyí ni mo fẹ́ bèèrè lọ́wọ́ yín: Nípa iṣẹ́ òfin ni ẹ̀yin gba Ẹ̀mi bí, tàbí nípa ìgbọ́ràn pẹ̀lú ìgbàgbọ́?
3. Báyìí ni ẹ̀yin ṣe gọ̀ tó bí? Lẹyin tí ẹ bẹ̀rẹ̀ nípa tí Ẹ̀mí, a há ṣe yín pé nísinsìnyìí nípa tí ara?
4. Ẹ̀yin ha ti jìyà ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan wọ̀nyí lásán? Bí ó bá ṣe pé nítoótọ́ lásán ni.
5. Ṣé Ọlọ́run fún yín ní Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó sì ṣe iṣẹ́-ìyanu láàrin yín nítorí tí ẹ̀yin pa òfin mọ, tàbí nítorí ẹ ní ìgbàgbọ sí ohun tí ẹ gbọ́?
6. Gẹ́gẹ́ bí Ábúráhámù “Ó gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí fún un ní òdodo.”