Gálátíà 2:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Nítorí pé nípa òfin, mo tí di òkú sí òfin, kí èmi lè wà láàyè sí Ọlọ́run.

20. A ti kàn mí mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Kírísítì, èmí kò sì wà láàyè mó, ṣùgbọ́n Kírísítì ń gbé inú mi wíwà tí mo sì wà láàyè nínú ara, mo wà láàyè nínú ìgbàgbọ́ ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí o fẹ́ mi, tí ó sì fi òun tìkararẹ̀ fún mi.

21. Èmi kò ya oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sí apákan: nítorí pé bí a bá le ti pasẹ̀ òfin jèrè òdodo, a jẹ́ pé Kírísítì kú lásán.”

Gálátíà 2