Ẹ́sítà 8:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Módékáì sì kúrò níwájú ọba, ó wọ aṣọ aláró àti funfun, ó dé adé e wúrà ńlá pẹ̀lú ìgbànú eléṣèé àlùkò dáradára, ìlú Ṣúṣà sì ṣe àjọyọ̀ ńlá.

16. Àsìkò ìdùnú àti ayọ̀, inú dídùn àti ọlá ni ó jẹ́ fún àwọn Júù.

17. Ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú, ní gbogbo ibi tí àṣẹ ọba dé, ni ayọ̀ àti inú dídùn ti wà láàrin àwọn Júù, wọ́n sì ń ṣe àsè àti àjọyọ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú tó kù sọ ara wọn di Júù nítorí ẹ̀rù àwọn Júù bà wọ́n.

Ẹ́sítà 8