1. Nígbà tí Módékáì gbọ́ gbogbo nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì fi eérú kunra, ó jáde lọ sí inú ìlú ó kígbe ṣókè ó sì sunkún kíkorò.
2. Ṣùgbọ́n ó lọ sí ẹnu ọ̀nà ọba nìkan, nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀ tì a gbà láàyè láti wọ ibẹ̀.
3. Ní gbogbo ìgbèríko tí ikú àti àṣẹ ọba dé, ọ̀fọ̀ ǹlá dé bá àwọn Júù, pẹ̀lú ààwẹ̀, ẹkún àti ìpohùn réré ẹkún. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà ninú aṣọ ọ̀fọ̀ tí wọ́n fi eérú kúnra.