Ẹ́sítà 1:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà Sérísésì, tí ó jọba lórí ẹ̀tàdínláàdóje ìletò bẹ̀rẹ̀ láti Índíà títí ó fi dé Etiópíà. (Kúsì)

2. Ní àkókò ìgbà náà ọba Ṣérísésì ń ṣe ìjọba ní orí ìtẹ́ ẹ rẹ̀ ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúsà,

3. Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó se àsè fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti ìjòyè. Àwọn olórí olóógun láti Páṣíà àti Médíà, àwọn ọmọ aládé, àti àwọn ọlọ́lá ìletò wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

4. Ó ṣe àfihàn púpọ̀ ọrọ̀ ìjọba rẹ̀ àti dídán àti ògo ọlá ńlá a rẹ̀ fún ọgọ́sàn-án ọjọ́ gbáko.

Ẹ́sítà 1