Ẹkún Jeremáyà 3:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ó ti tì mí mọ́lé nítorí náà n kò le è sálọ;ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀

8. Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́,ó kọ àdúrà mi.

9. Ó fi búlọ́kù òkúta dí ọ̀nà mi;ó sì mú ọ̀nà mi wọ́

10. Bí i béárì tí ó dùbúlẹ̀,bí i kìnnìún tí ó sá pamọ́.

11. Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ó fi mi sílẹ̀ láì sí ìrànlọ́wọ́.

Ẹkún Jeremáyà 3