Ẹkún Jeremáyà 3:42-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá.

43. “Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa;ìwọ ń parun láì sí àánú.

44. Ìwọ ti fi ìkuukù bo ara rẹpé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ.

45. Ó ti sọ wá di èérí àti ààtànláàrin orílẹ̀ èdè gbogbo.

46. “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọngbòòrò sí wa.

Ẹkún Jeremáyà 3