Ẹkún Jeremáyà 3:39-49 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Kí ló dé tí ẹ̀dá alàyè ṣe ń kùnnígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

40. Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa kí a sì dán an wò,kí a sì tọ Olúwa lọ.

41. Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókèsí Ọlọ́run ní ọ̀run, kí a wí pé:

42. Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá.

43. “Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa;ìwọ ń parun láì sí àánú.

44. Ìwọ ti fi ìkuukù bo ara rẹpé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ.

45. Ó ti sọ wá di èérí àti ààtànláàrin orílẹ̀ èdè gbogbo.

46. “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọngbòòrò sí wa.

47. Àwa ti jìyà àti ìparun,nínú ìbẹ̀rù àti ewu.”

48. Omijé ń ṣàn ní ojú mi bí odònítorí a pa àwọn ènìyàn mi run.

49. Ojú mi kò dá fún omijé,láì sinmi,

Ẹkún Jeremáyà 3