10. Ó sì to ìpele òkúta mẹ́rin oníyebíye sí i. Ní ipele kìn-in-ní ní rúbì wà, tapásì àti bérílù;
11. ní ipele kejì, túríkúóṣè, sáfírù àti émérálídì;
12. ní ipele kẹta, Jásínítì, ágátè àti amétístì;
13. ní ipele kẹ́rin, kárísólítì, oníkísì, àti jásípérì. Ó sì tò wọ́n ní ojú ìdè wúrà ní títò wọn.
14. Wọ́n jẹ́ òkúta méjìlá ọkan fún orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan, a fín ọ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ ẹnikọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjèèjìlá.