Ékísódù 36:32-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. márùn-ún fún àwọn tí ó wà ní ìhà kejì, márùn-ún fún pákó tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ní ìkangun Àgọ́ náà.

33. Wọ́n sì ṣe ọ̀pá àárin tí yóò fi jáde láti ìkangun dé ìkangun ní àárin àwọn pákó náà.

34. Wọ́n bo àwọn pákó pẹ̀lú wúrà, wọ́n sì ṣe àwọn òrùkà wúrà láti gbá ọ̀pá náà mú. Wọ́n sì tún bo ọ̀pá náà pẹ̀lú wúrà.

35. Wọ́n ṣe aṣọ títa ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, wọ́n ṣe kérúbù si pẹ̀lú ọgbọ́n oníṣẹ́ ọnà.

Ékísódù 36