36. Ìṣọ àti ẹ̀ka yóò di ara kan náà pẹ̀lú òpó fìtílà ti a fi ojúlówó wúrà ti a lù ṣe.
37. “Nígbà náà ni ìwọ yóò se fítílà méje. Ìwọ yóò sì gbe ka orí rẹ̀, kí wọn bá a lè tan iná sí iwájú rẹ̀.
38. Ike ọ̀pá àbẹ́là àti ọpọ́n agogo gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí a fi ojúlówó wúrà ṣe.
39. Ìwọ̀n ojúlówó wúrà ti ó tó talẹ́ǹtì kan ni a gbọdọ̀ fi se ọ̀pá fìtílà àti àwọn ti ó so mọ́ ọn.
40. Rí i pé ó ṣe gẹ́gẹ́ bí bátànì ti mo fihàn ọ́ ni orí òkè.