11. gẹ́gẹ́ bí ìpinnu àtayébáyé tí ó ti pinnu nínú Kírísítì Jésù Olúwa wa:
12. Nínú ẹni tí àwa ní ìgboyà, àti ọ̀nà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀.
13. Nítorí náà mo bẹ̀ yín kí àárẹ̀ má ṣe mú yín ni gbogbo wàhálà mi nítorí yín, tíi ṣe ògo yín.
14. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eekún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jésù Kírísítì.
15. Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé.
16. Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ mú ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.