Deutarónómì 34:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Mósè jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún nígbà tí ó kú, síbẹ̀ ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù.

8. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣunkún un Móṣè ní pẹ̀tẹ́lẹ́ Móábù ní ọgbọ̀n ọjọ́ títí di ìgbà tí ọjọ́ ẹkún àti ọ̀fọ̀ Móṣè parí.

9. Jóṣúà ọmọ Núnì kún fún ẹ̀mí ọgbọ́n nítorí Móṣè ti gbọ́wọ́ ọ rẹ̀ lée lórí. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì fetí sí i wọ́n sì ṣe ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún Mósè.

10. Láti ìgbà náà kò sì sí wòlíì tí ó dìde ní Ísírẹ́lì bí i Móṣè, ẹni tí Olúwa mọ̀ lójúkojú,

11. tí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí Olúwa rán an láti lọ ṣe ní Éjíbítì sí Fáráò àti sí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ àti sí gbogbo ilẹ̀ náà.

12. Nítorí kò sí ẹni tí ó tíì fi gbogbo ọ̀rọ̀ agbára hàn, tàbí ṣe gbogbo ẹ̀rù ńlá tí Móṣè fi hàn ní ojú gbogbo Ísírẹ́lì.

Deutarónómì 34