Deutarónómì 32:20-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú ù mi mọ́ kúrò lára wọn,èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí;nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí,àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú un wọn.

21. Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run,wọ́n sì fi ohun aṣán an wọn mú mi bínú.Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn;èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀ èdè.

22. Nítorí pé iná kan ràn nínú ìbínú un mi,yóò sì jó dé ipò ikú ní ìṣàlẹ̀.Yóò sì run ayé àti ìkórè e rẹ̀yóò sì tiná bọ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.

Deutarónómì 32