Deutarónómì 30:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. èmi ń sọ fún un yín lónìí yìí pé ìwọ yóò parun láìsí àní-àní. O kò ní í gbé pẹ́ ní ilẹ̀ tí ìwọ ń kọjá Jọ́dánì láti gbà àti láti ní.

19. Lónìí mo pe ọ̀run àti ayé bí ẹlẹ́rìí sí ọ pé mo ti gbékalẹ̀ síwájú rẹ ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún. Nísinsìnyìí yan ìyè, nítorí kí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lè gbé

20. kí ìwọ sì lè fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, fetí sílẹ̀ sí ohùn un rẹ̀, kí o sì dúró ṣinṣin nínú rẹ̀. Nítorí Olúwa ni ìyè rẹ, yóò sì fún ọ ní ọdún púpọ̀ ní ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba rẹ Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù.

Deutarónómì 30