11. Wàyí gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún un yín lónìí kò le jù fún un yín tàbí kọjá agbára yín.
12. Kò sí ní ọ̀run, tí ìwọ kò bá fi wí pé, “Ta ni yóò gòkè lọ sí ọ̀run fún wa, tí yóò sì mú wa fún wa, kí àwa lè gbọ́, kí a sì le ṣe é?”
13. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ìhà kejì òkun, tí ìwọ ìbá fi wí pé, “Ta ni yóò rékọjá òkun lọ fún wa, tí yóò sì mú un wá fún wa, kí àwa lè gbọ́ ọ, kí a si le ṣe é?”
14. Kìí ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ náà súnmọ́ tòsí ì rẹ, ó wà ní ẹnu ù rẹ àti ní ọkàn rẹ kí ìwọ lè máa ṣe é.
15. Wòó mo gbé kalẹ̀ síwájú u yín lónìí, ìyè àti àlàáfíà, ikú àti ìparun.
16. Nítorí mo pàṣẹ fún ọ lónìí láti fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, láti rìn ní ọ̀nà a rẹ̀ àti láti pa àwọn àṣẹ, ìpinnu àti òfin rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni ìwọ yóò máa gbé tí o ó sì máa pọ̀ sí i, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún ọ ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.