1. Èyí ni àwọn ìpinnu májẹ̀mú tí Olúwa pa láṣẹ fún Mósè láti ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Móábù, ní àfikún májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú u wọn ní Hórébù,
2. Móṣè pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì sọ fún wọn wí pé:Ojú rẹ ti rí gbogbo ohun tí Olúwa ti ṣe ní Éjíbítì sí Fáráò àti, sí gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀ àti sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀.
3. Pẹ̀lú ojú ara rẹ ni ìwọ rí àwọn ìdánwò ńlá náà, àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá.
4. Ṣùgbọ́n títí di àsìkò yìí Olúwa kò fi ọkàn ìmòye tàbí ojú tí ó ń rí tàbí etí tí ó n gbọ́ fún ọ.
5. Nígbà ogójì ọdún tí mò ń tọ́ yín sọ́nà ní ihà, aṣọ ọ̀ rẹ kò gbó tàbí bàtà ẹṣẹ̀ rẹ.
6. O kò jẹ oúnjẹ tàbí mu wáìnì kankan tàbí rú ohun mímu mìíràn. Mo ṣe èyí kí o lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ.
7. Nígbà tí o dé ibí yìí, Ṣíhónì ọba Hésíbónì àti Ógù ọba Básánì jáde wá láti bá ọ jà, ṣùgbọ́n a sẹ́gun wọn.
8. A gba ilẹ̀ wọn a sì fi fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àti àwọn ọmọ Gádì, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè bí ogún.
9. Rọra máa tẹ̀lé ìpinnu májẹ̀mú yìí, kí o lè ṣe rere nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe.
10. Gbogbo yín ń dúró lónìí yìí níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ: adarí ì rẹ àti olórí àwọn ọkùnrin, àwọn àgbààgbà rẹ àti àwọn olóyè àti gbogbo àwọn ọkùnrin mìíràn ní Ísírẹ́lì,
11. pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọ̀ rẹ àti ìyàwó ò rẹ àti àwọn àlejò tí wọ́n ń gbé ní àgọ́ ọ̀ rẹ, tí ó ké pópòpó igi rẹ, tí ó sì gbé omi ì rẹ.
12. O dúró níhìn ín yìí kí o lè wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ, májẹ̀mú tí Olúwa ń ṣe pẹ̀lú ù rẹ lónìí yìí àti tí óun dè pẹ̀lú ìbúra,
13. láti jẹ́wọ́ rẹ lónìí yìí bí ènìyàn an rẹ̀, pé kí ó lè jẹ́ Ọlọ́run rẹ bí ó ti ṣèlérí àti bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba à rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jákọ́bù.
14. Èmi ń ṣe májẹ̀mú yìí, pẹ̀lú ìbúra rẹ̀, kì í ṣe fún ìwọ nìkan
15. tí ó dúró níbí pẹ̀lú wa lónìí níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ṣùgbọ́n àti fún gbogbo àwọn tí kò sí níbí lónìí.
16. Ìwọ fúnra à rẹ mọ bí a ṣe gbé ní Éjíbítì àti bí a se kọjá láàrin àwọn orílẹ̀ èdè nílẹ̀ ibí yìí.