16. Baba kò gbọdọ̀ kú fún àwọn ọmọ wọn tàbí kí àwọn ọmọ kú fún bàbá wọ́n; olúkúlùkù ní láti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀.
17. Má ṣe yí ìdájọ́ po fún àlejò tàbí aláìní baba, tàbí gba aṣọ ìlékè opó bí ẹ̀rí.
18. Rántí pé o jẹ́ ẹrú ní Éjíbítì tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì gbà ọ́ níbẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.
19. Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ tí o sì fojú fo ìtí kan, má ṣe padà lọ mú u. Fi í kalẹ̀ fún àwọn àlejò, aláìní baba àti opó, kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún fún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ.
20. Nígbà tí o bá ń gun igi ólífì lára àwọn igi i rẹ, má ṣe padà lọ sí ẹ̀ka náà ní ìgbà kejì. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó.
21. Nígbà tí o bá kórè èṣo àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ, má ṣe lọ sí ọgbà náà mọ́. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó.
22. Rántí pé o ti jẹ́ àlejò ní Éjíbítì. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.