8. Dáríjìn, Olúwa, àwọn ènìyàn rẹ ni Ísírẹ́lì, tí ìwọ ti dá sílẹ̀, àti kí ìwọ má ṣe gba ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìsẹ̀ ní àárin àwọn ènìyàn rẹ ní Ísírẹ́lì. Ṣùgbọ́n kí a dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yìí jìn.
9. Nígbà náà ni ìwọ wẹ̀ kúró láàrin rẹ ẹ̀bi títa ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí o ti ṣe èyí tí ó tọ́ níwájú Olúwa.
10. Nígbà tí o bá lọ sí ogun sí àwọn ọ̀ta rẹ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ tí o sì mú àwọn ìgbékùn,
11. tí o sì rí obìnrin tí ó dára lára àwọn ìgbékùn, tí o sì ní ìfẹ́ síi, o lè mu u gẹ́gẹ́ bí aya à rẹ.
12. Mú u wá sí ilé e rẹ kí o sì jẹ́ kí ó fá irun orí i rẹ̀, gé èékánná an rẹ̀,
13. kí o sì mú aṣọ tí ó wọ̀ nígbà tí ó di ìgbékùn sí ẹ̀gbẹ́ kan. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ń gbé ilé rẹ tí ó sì ti sọ̀fọ̀ baba àti ìyá rẹ̀ fún odidi osù kan, nígbà náà ni o lè tọ̀ ọ́ lọ kí o sì ṣe ọkọ rẹ̀ kí ó jẹ́ aya rẹ.