Deutarónómì 21:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Tí a bá rí ọkùnrin tí a pa, ní ìdùbúlẹ̀ ní pápá nínú ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ láti jogún, tí a kò sì mọ ẹni tí ó pa á,

2. àwọn àgbààgbà yín yóò jáde lọ láti wọn jíjìnnà ibi òkú sí ìlú tí ó wà nítòòsí.

3. Nígbà náà ni àwọn àgbààgbà ìlú tí ó wà nítòòsí òkú yóò mú ẹgbọ̀rọ̀ abo màlúù tí kò ì siṣẹ́ àti tí kò ì tíì fà sí àmì ìsìn ẹrú,

4. kí wọn sìn ín wá sí àfonífojì tí a kò ì tíì ro tàbí gbìn àti ibi tí odò ṣíṣàn wà. Níbẹ̀ ní àfonífojì wọn yóò kán ọrùn ẹgbọ̀rọ̀ màlúù.

Deutarónómì 21