Deutarónómì 2:34-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Nígbà náà, gbogbo ìlú wọn ni a kó tí a sì pa wọ́n run pátapáta tọkùnrin, tobìnrin àti gbogbo ọmọ wọn. A kò sì dá ẹnikẹ́ni sí.

35. Ṣùgbọ́n a kó gbogbo ohun ọ̀sìn àti ìkógun àwọn ìlú tí a ṣẹ́gun fún ara wa.

36. Láti Áróérì, létí odò Ánónì àti láti àwọn ìlú tí ó wà lẹ́bàá odò náà títí ó fi dé Gílíádì, kò sí ìlú tí ó lágbára jù fún wa, Olúwa Ọlọ́run wa fi gbogbo wọn fún wa.

Deutarónómì 2