Deutarónómì 15:20-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ní ọdọọdún ni kí ìwọ àti ìdílé rẹ máa jẹ ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbi tí Òun yóò yàn.

21. Bí ẹran ọ̀ṣìn kan bá ní àbùkù: bóyá ó yarọ, tàbí fọ́jú, tàbí tí ó ní èyíkèyìí àbùkù tó burú. Ẹ kò gbọdọ̀ fi rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín.

22. Ẹ jẹ ẹ́ ní ìlú u yín. Àti ẹni tí a kà sí mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ ẹ́ bí ìgbà tí a ń jẹ èsúó tàbí àgbọ̀nrín.

23. Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀; Ẹ dà á síta bí omi.

Deutarónómì 15