Deutarónómì 1:43-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

43. Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún un yín, ẹ kò sì gbọ́, ẹ sọ̀tẹ̀ sí òfin Olúwa, pẹ̀lú ìgbéraga yín ẹ gòkè lọ sí ìlú olókè náà.

44. Àwọn ará Ámórì tí ń gbé ní àwọn òkè náà, dojú kọ yín bí àgbájọpọ̀ oyin. Wọ́n sì lù yín bolẹ̀ látí Séírì títí dé Hómà.

45. Ẹ padà, ẹ sì sunkún níwájú Olúwa, òun kò sì fetí sí igbe ẹkún yín, Ó sì kọ etí dídi sí i yín.

46. Báyìí ni ẹ sì dúró ní Kádésì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ṣe.

Deutarónómì 1