2. pẹ̀lú alákòóso mẹ́ta, Dáníẹ́lì sì jẹ́ ọ̀kan nínú un wọn, kí àwọn baálẹ̀ lè wá máa jẹ́ ààbọ̀ fún wọn, kí ọba má ba à ní ìpalára.
3. Dáníẹ́lì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ láàrin àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ nítorí ẹ̀mí tí ó tayọ wà lára rẹ̀ dé bi pé ọba sì ń gbérò láti fi ṣe olórí i gbogbo ìjọba.
4. Nítorí èyí, gbogbo àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ ń gbérò láti wá ẹ̀ṣẹ̀ kà sí Dáníẹ́lì lọ́rùn nínú ètò ìṣèjọba rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan kà sí i lọ́rùn, wọn kò rí ìwà ìbàjẹ́ kankan tí ó ṣe, nítorí ó jẹ́ olóòtítọ́ kò sì ní ìwà ìjáfara.
5. Nígbẹ̀yìn ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyí sọ wí pé, “Àwa kò ní rí ìdí kankan láti kà ẹ̀ṣẹ̀ sí i lọ́rùn, àfi èyí tí ó bá ní í ṣe pẹ̀lú òfin Ọlọ́run rẹ̀.”
6. Nígbà náà ni àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bí ikọ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba, wọ́n wí pé: “Ìwọ Dáríúsì ọba, kí o pẹ́!
7. Àwọn alákòóso ọba, ìjòyè, baálẹ̀, olùdámọ̀ràn, àti àwọn olórí gbìmọ̀ pọ̀ wí pé kí ọba kéde òfin kan pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àdúrà sí Ọlọ́run tàbí ènìyàn kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, yàtọ̀ fún ìwọ ọba, a ó ju ẹni náà sí inú ihò kìnnìún.
8. Nísinsin yìí, ìwọ ọba, gbé òfin yìí jáde, kí o sì kọ ọ́ sínú ìwé kí a má ba à yí i padà ní ìbámu pẹ̀lú òfin àwọn Médíánì àti Páṣíà, èyí tí kò ní le è parẹ́.”