5. Lójijì, ìka ọwọ́ ènìyàn jáde wá, ó sì ń kọ̀wé sára ẹfun ògiri ní ẹ̀gbẹ́ ibi tí àtùpà ń dúró ní ààfin ọba. Ọba ń wo ọwọ́ náà bí ó ṣe ń kọ ọ́.
6. Ojú ọba sì yí padà, ẹ̀rù sì bàá, tó bẹ́ẹ̀ tí orúnkún ẹṣẹ̀ rẹ̀ méjèèjì rẹ̀ fi ń gbá ara wọn.
7. Ọba kígbe pé, kí wọn pe àwọn awòràwọ̀, àwọn onídán, àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, ọba sì sọ fún àwọn amòye Bábílónì pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lè ka àkọsílẹ̀ yìí kí ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, ẹni náà ni a ó fi aṣọ eléṣèé àlùkò wọ̀ àti ẹ̀gbà wúrà ni a ó fi sí ọrùn un rẹ̀, òun ni yóò sì ṣe olórí kẹta ní ìjọba à mi.”
8. Nígbà náà ni gbogbo àwọn amòye ọba wọ ilé, ṣùgbọ́n, wọn kò le ka àkọsílẹ̀ náà tàbí sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba.
9. Nígbà náà ni Beliṣáṣárì ọba bínú gidigidi, ojú u rẹ̀ sì túbọ̀ dàrú síi. Ẹ̀rù sì ba àwọn ìjòyè rẹ̀.
10. Nígbà tí ayaba gbọ́ ohùn ọba àti àwọn ọlọ́lá rẹ̀, ó wá ilé àsè wá. Ó wí pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! Má ṣe jẹ́ kí inú un rẹ bàjẹ́, má sì ṣe jẹ́ kí ojú u rẹ fàro.
11. Ọkùnrin kan wà ní ìjọba à rẹ, ẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run, mímọ́ ń gbé inú un rẹ̀. Ní ìgbà ayé e bàbá à rẹ, òun ni ó ní ojú inú, òye àti ìmọ̀ bí i ti Ọlọ́run òun ni ọba Nebukadinéṣárì, bàbá rẹ̀ fi jẹ olórí àwọn onídán, awòràwọ̀, apògèdè àti aláfọ̀ṣẹ.
12. Ọkùnrin náà ni Dáníẹ́lì ẹni tí ọba ń pè ní Beliteṣáṣárì, ó ní ẹ̀mí tí ó tayọ, ìmọ̀ àti òye, àti agbára láti túmọ̀ àlá, ó máa ń ṣe àlàyé àlá àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá dojúrú, ránsẹ́ pè é, yóò sì sọ nǹkan tí àkọsílẹ̀ ìwé náà túmọ̀ sí.”
13. Nigbà náà ni a mú Dáníẹ́lì wá ṣíwájú ọba, ọba sì sọ fún-un wí pé, “Ṣé ìwọ ni Dáníẹ́lì, ọ̀kan lára àwọn tí bàbá mi mú ní ìgbékùn láti Júdà!
14. Mo ti gbọ́ wí pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú un rẹ àti wí pé ìwọ ní ojú inú, òye, àti ọgbọ́n tí ó tayọ.
15. A ti mú àwọn amòye àti àwọn awòràwọ̀ wá sí iwájú mí kí wọn ba à le è wá ka àkọsílẹ̀ yìí kí wọn sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtumọ̀ ohun tí ó jẹ́.
16. Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ wí pé, ìwọ lè sọ ìtumọ̀, àti wí pé o lè yanjú àwọn ìṣòro tó lágbára. Tí o bá lè ka àkọsílẹ̀ ìwé yìí kí o sì sọ ìtúmọ̀ rẹ̀, a ó fi aṣọ eléṣèé àlùkò wọ̀ ọ́ pẹ̀lú ẹ̀gbà wúrà ni a ó fi sí ọ lọ́rùn, a ó sì fi ọ́ ṣe olórí kẹta ní ìjọba mi.”
17. Nígbà náà ni Dáníẹ́lì dá ọba lóhùn wí pé, “Fi ẹ̀bùn rẹ pamọ́ fún ara rẹ, tàbí kí o fún ẹlòmíràn. Síbẹ̀ èmi yóò ka àkọsílẹ̀ náà fún ọba, èmi yóò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.
18. “Ìwọ ọba, Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo fún Nebukadinésárì baba rẹ ní ìjọba, títóbi ògo àti ọlá.