Dáníẹ́lì 10:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, bí mo ṣe tẹ́tí sílẹ̀ síi, mo ṣùn lọ fọnfọn, ní ìdojúbolẹ̀.

10. Ọwọ́ kan kàn mí, ó gbé mi dìde ní ìwárìrì lórí ọwọ́ àti eékún mi.

11. Ó sọ pé, “Dáníẹ́lì ẹni tí a yànfẹ́ gidigidi gba ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ bá ọ sọ yìí yẹ̀wò dáadáa, kí o sì dìde, nítorí tí a rán mi sí ọ.” Bí ó ṣe sọ èyí fún mi, mo dìde ní ìwárìrì.

12. Nígbà náà ni ó tẹ̀ṣíwájú, pé, “Má ṣe bẹ̀rù Dáníẹ́lì. Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí ìwọ ti fi ọkàn rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run rẹ, a gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì wá nítorí ọ̀rọ̀ náà.

13. Ṣùgbọ́n ọmọ aládé ìjọba Páṣíà dá mi dúró fún ọjọ́mọ́kànlélógún. Nígbà náà ni Máíkẹ́lì, ọ̀kan lára ìjòyè àwọn ọmọ aládé, wá láti ràn mi lọ́wọ́, nítorí a dá mi dúró níbẹ̀ pẹ̀lú ọba Páṣíà.

Dáníẹ́lì 10