6. Lára àwọn wọ̀nyí ni àwọn tó wá láti Júdà: Dáníẹ́lì, Hananíáyà, Mísáẹ́lì àti Ásáríyà.
7. Olórí àwọn ìwẹ̀fà fún wọn ní orúkọ tuntun: Ó fún Dáníẹ́lì ní Beliteṣáṣárì, ó fún Hananíáyà ní Sádírákì, ó fún Mísáẹ́lì ní Mésákì àti Áṣáríyà ní Àbẹ́dinígò.
8. Ṣùgbọ́n Dáníẹ́lì pinnu ní ọkàn ara rẹ̀ pé òun kò ní ba ara òun jẹ́ pẹ̀lú oúnjẹ àti wáìnì ọba, nígbà náà ni ó gba ààyè lọ́wọ́ olórí àwọn ìwẹ̀fà wí pé òun kò fẹ́ ba ara òun jẹ́ ní ọ̀nà yìí.
9. Ọlọ́run mú kí Dáníẹ́lì rí ojúrere àti àánú gbà láti ọwọ́ olórí àwọn ìwẹ̀fà,
10. Ṣùgbọ́n olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ fún Dáníẹ́lì pé, “Mo bẹ̀rù Olúwa mi, ẹni tí o ti pèṣè oúnjẹ àti ohun mímu rẹ. Báwo ni ìrísí ì rẹ yóò ṣe burú jù ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ẹlẹgbẹ́ ẹ̀ rẹ lọ? Nígbà náà ni èmi yóò fi orí mi wéwu lọ́dọ̀ ọba.”
11. Nígbà náà ni Dáníẹ́lì sọ fún olùṣọ́ tí olórí àwọn ìwẹ̀fà yàn lórí i Dáníẹ́lì, Hananiáyà, Mísáẹ́lì àti Ásáríyà pé,
12. Jọ̀wọ́ dán àwa ìránṣẹ́ rẹ wò fún ọjọ́ mẹ́wàá: Má ṣe fún wa ní ohun kankan, àfi ẹ̀fọ́ láti jẹ àti omi láti mu.