Àwọn Hébérù 3:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí náà ẹ̀yin ará mímọ́, alábàápín ìpè ọ̀run, ẹ gba ti Àpósítélì àti Olórí Àlùfáà ìjẹ́wọ́ wa rò, àní Jésù;

2. Ẹni tí o ṣe olóòótọ́ si ẹni tí ó yàn án, bí Mósè pẹ̀lú tí ṣe olóòótọ́ nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo ilé Ọlọ́run.

3. Nítorí a ka ọkùnrin yìí ni yíyẹ sí ògo ju Mósè lọ níwọ̀n bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti lọ́lá ju ilé lọ.

4. Láti ọwọ́ ènìyàn kan ni a sá à ti kọ́ olúkúlùkù ilé; ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.

Àwọn Hébérù 3