15. Ṣùgbọ́n Olúwa mu mi bí mo ti ń tọ́ agbo ẹran lẹ́yìn, ó sì wí fun mi pé, ‘Lọ sọtẹ́tẹ̀ fun àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi.’
16. Nítorí náà nísinsin yìí, gbọ ọ̀rọ̀ Olúwa. Ìwọ wí pé,“ ‘Má ṣe sọ àṣọtẹ́lẹ̀ sí Ísírẹ́lìMá ṣì ṣe wàásù sí ilé Ísáákì.’
17. “Nítorí náà, èyí ni ohun ti Olúwa wí:“ ‘Ìyàwó rẹ yóò di paṣángà ni ìlú,àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú.A ó wọn ilẹ̀ rẹ, a ó sì pín inàti ìwọ pẹ̀lú yóò kú ni ilẹ̀ àìmọ́.Ísírẹ́lì yóò sì lọ sí ìgbèkùn,kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ”