Àìsáyà 9:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùnti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá;Lórí àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ òjìji ikú niìmọ́lẹ̀ ti ràn.

3. Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè di ńlá;wọ́n sì yọ̀ níwájúu rẹgẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ti í yọ ayọ̀ ìkóórè,gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti í yọ̀nígbà tí à ń pín ìkógun.

4. Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a ṣẹ́gun Mídíánì,ìwọ ti fọ́ ọ túútúúúàjàgà ti ń pa wọ́n lẹ́rù,ọ̀pá tí ó dábùú èjìká wọn,ọ̀gọ aninilára wọn.

Àìsáyà 9