Àìsáyà 62:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ẹ kọjá, ẹ kọjá ní ẹnu ibodè náà!Ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn ènìyàn.Ẹ mọ ọ́n, ẹ mọ ojú ọ̀nà òpópó!Ẹ sa òkúta kúròẸ gbé àṣíá ṣókè fún àwọn orílẹ̀ èdè

11. Olúwa ti ṣe ìkédetítí dé òpin ilẹ̀ ayé:“Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Ṣíhónì pé,‘kíyèsí i, Olùgbàlà rẹ ń bọ̀!Kíyèsí i, èrè ń bẹ pẹ̀lúu rẹ̀,àti ẹ̀san rẹ pẹ̀lú n tẹ̀lé e lẹ́yìn.’ ”

12. A ó sì pè wọ́n ní Ènìyàn Mímọ́,ẹni ìràpadà Olúwa;a ó sì máa pè ọ́ ní ìwákiri,Ìlú tí a kì yóò kọ̀ sílẹ̀.

Àìsáyà 62