Àìsáyà 48:20-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Fi Bábílónì sílẹ̀,sá fún àwọn ará Bábílónì,ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀kí o sì kéde rẹ̀.Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé;wí pé, “Olúwa ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jákọ́bù nídè.”

21. Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọnkọjá nínú ihà;ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta;ó fọ́ àpátaomi sì tú jáde.

22. “Kò sí àlàáfíà,” ni Olúwa wí,“Fún àwọn ìkà.”

Àìsáyà 48