Àìsáyà 42:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ìránṣẹ́ mi nìyìí, ẹni tí mo gbéró,àyànfẹ́ mi nínú ẹni tí mo láyọ̀;Èmi yóò fi Ẹ̀mí mi sínú rẹ̀òun yóò sì mú ìdájọ́ wá sórí àwọn orílẹ̀ èdè.

2. Òun kì yóò pariwo tàbí kígbe ṣókè,tàbí kí ó gbóhùn rẹ̀ ṣókè ní òpópónà.

3. Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́àti òwú-àtùpà tí ń jó tan an lọlòun kì yóò fẹ́ pa.Ní òdodo ni yóò mú ìdájọ́ wá;

4. Òun kì yóò kọsẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sìtítí tí yóò fi fi ìdájọ́ mulẹ̀ ní ayé.Nínú òfin rẹ̀ ni àwọn erékùṣù yóò fi ìrètíi wọn sí.”

Àìsáyà 42