Àìsáyà 34:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Òwìwí yóò tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ ṣíbẹ̀,yóò yé, yóò sì pa,yóò sì kójọ lábẹ́ òjìji rẹ̀:àwọn gúnnugún yóò péjọ ṣibẹ̀ pẹ̀lú,olúkúlùkù pẹ̀lú ẹnìkejì rẹ̀.

16. Ẹ wá a nínú ìwé Olúwa, ẹ sì kà á:Ọ̀kan nínú wọ̀nyí kì yóò yẹ̀,kò sí ọ̀kan tí yóò fẹ́ ìkejìi rẹ̀ kù:nítorí Olúwa ti pàṣẹẹnu rẹ̀ ló sì fi kó wọn jọẸ̀mí rẹ̀ ló sì fi tò wọ́n jọ.

17. Ó ti di ìbò fún wọn,ọwọ́ rẹ̀ sì ti pín in fún wọnnípa títa okùn,wọn ó jogún rẹ̀ láéláé,láti ìran dé ìranni wọn ó máa gbé inú un rẹ̀.

Àìsáyà 34