Àìsáyà 16:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Gbogbo pápá-oko Héṣíbónì ti gbẹ,bákan náà ni àjàrà Ṣíbínà rí.Àwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀ èdèwọ́n tẹ àwọn àyànfẹ́ àjàrà mọ́lẹ̀,èyí tí ó ti fà dé Jáṣérìó sì ti tàn dé agbègbè aṣálẹ̀.Àwọn èhu rẹ̀ fọ́n jádeó sì lọ títí ó fi dé òkun.

9. Nítorí náà mo ṣunkún, gẹ́gẹ́ bí Jáṣérì ṣe ṣunkún,fún àwọn àjàrà Ṣíbínà.Ìwọ Hẹ́ṣíbónì, Ìwọ Élíálẹ̀,mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú!Igbe ayọ̀ lórí àwọn èṣo pípọ́n rẹàti lórí ìkóórè èyí tí o ti mọ́wọ́dúró.

10. Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrònínú ọgbà-igi eléso rẹ;kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbíkígbe nínu ọgbà-àjàrà:ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí,nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe.

11. Ọkàn mi kérora fún Móábù gẹ́gẹ́ bí i hápù,àní tọkàntọkàn mi fún ìlú Háréṣétì.

Àìsáyà 16