6. Nitorí à ń fí mi rúbọ nisínsinyìí, àtilọ mi sì súnmọ́ etíle.
7. Èmi ti ja ìjà rere, èmi tí parí iré-ìje mi, èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́;
8. Láti ìsinsinyìí lọ a fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa onídàjọ́ òdodo, yóò fífún mi ni ọjọ́ náà kì í sì í ṣe kìkì èmi nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn rẹ̀.
9. Sa ipá rẹ láti tètè tọ̀ mí wá.
10. Nítorí Démà ti kọ̀ mí sílẹ̀, nitorí ó ń fẹ́ ayé yìí, ó sì lọ sí Tẹsalóníkà; Kírésíkénì sí Gálátíà, Títù sí Dalimátíà.
11. Lúùkù nìkan ni ó wà pẹ̀lú mi, mú Máàkù wá pẹ̀lú rẹ: nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́-ìránṣẹ́.
12. Mo rán Tíkíkù ní iṣẹ lọ sí Éfésù.
13. Aṣọ òtútù tí mọ fi sílẹ̀ ní Tíróà lọ́dọ̀ Kárípù, nígbà tí ìwọ bá ń bọ̀ mu un wa, àti àwọn ìwé, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìwé-awọ.
14. Alekisáńdérù alágbẹ̀dẹ bàbà ṣe mi ni ibi púpọ̀: Olúwa yóò san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀:
15. Lọ́dọ̀ ẹni tí kí ìwọ máa ṣọ́ra pẹ̀lú, nítorí tí ó kọ ojú ìjà sí ìwàásù wa púpọ̀.
16. Ní àkọ́kọ́ jẹ́ ẹjọ́ mi, kò sí ẹni tí ó ba mi gba ẹjọ́ rò ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni o kọ̀ mi sílẹ̀: Àdúrà mi ni kí a má ṣe ká à sí wọn lọ́rùn.
17. Ṣùgbọ́n Olúwa gba ẹjọ́ mi rò, ó sì fún mi lágbára; pé nipasẹ̀ mi kí a lè wàásù náà ní àwàjálẹ̀, àti pé kí gbogbo àwọn aláìkọlà lè gbọ́; a sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnìún náà.
18. Olúwa yóò yọ mí kúrò nínú iṣẹ́ bubúrú gbogbo, yóò sì gbà mí dé inú ìjọba rẹ̀; ẹni ti ògo wà fún láé àti láéláé. (Àmín).
19. Kí Parísíkà àti Àkúílà, àti ilé Onésífórù.
20. Érásítù wà ní Kọ́ríntí: ṣùgbọ́n mo fi Tírófímù sílẹ̀ ni Mílétù nínú àìsàn.