20. Dáfídì sì dé Baal-Perasímù, Dáfídì sì pa wọ́n níbẹ̀, ó sì wí pé, “Olúwa ti ya lu àwọn ọta mi níwájú mi, gẹ́gẹ́ bí omi ti ń ya.” Nítorí náà ni òun ṣe pe orúkọ ibẹ̀ náà ni Baal-Perasímù.
21. Wọ́n sì fi òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀, Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì kó wọn.
22. Àwọn Fílístínì sì tún gòkè wá, wọ́n sì tan ara wọn kalẹ̀ ní àfonífojì Rafaímù.
23. Dáfídì sì bèèrè lọ́dọ̀ Olúwa, òun sì wí pé, “Má ṣe gòkè lọ; ṣùgbọ́n bù wọ́n lẹ́yìn, kí o sì kọlù wọ́n níwájú àwọn igi Bákà.