2 Sámúẹ́lì 4:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì gbọ́ pé, Ábínérì kú ní Hébírónì, ọwọ́ rẹ̀ sì rọ, gbogbo Ísírẹ́lì sì rẹ̀wẹ̀sì.

2. Ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì ní ọkùnrin méjì tí í ṣe olórí ẹgbẹ́ ogun: a ń pe orúkọ ọ̀kan ní Báánà, àti orúkọ ìkẹjì ní Rákábù, àwọn ọmọ Rímímónì ará Béérótì ti àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì (nítorí pé a sì ka Béérótì pẹ̀lú Bẹ́ńjámínì).

3. Àwọn ará Béérótì sì ti sá lọ sí Gítaímù, wọ́n sì ṣe àtìpó níbẹ̀ títí ó fi di ọjọ́ òní yìí.

2 Sámúẹ́lì 4