2 Sámúẹ́lì 3:31-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Dáfídì sì wí fún Jóábù àti fún gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ fa aṣọ yín ya, kí ẹ̀yin sì mú aṣọ-ọ̀fọ̀, kí ẹ̀yín sì sunkún níwájú Ábínérì.” Dáfídì ọba tìkararẹ̀ sì tẹ̀lẹ́ pósí rẹ̀.

32. Wọ́n sì sin Ábínérì ní Hébírónì: ọba sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sunkùn ní ibojì Ábínérì; gbogbo àwọn ènìyàn náà sì sunkún.

33. Ọba sì sọkún lórí Ábínérì, ó sì wí pé,“Ǹjẹ́ Ábínérì; yẹ kí ó kú bí aṣiwèrè?

34. A kò sáà dè ọ́ lọ́wọ́,bẹ́ẹ̀ ni a kò kan ẹsẹ̀ rẹ ní àbà.Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń ṣubú níwájú àwọn ìkà ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ ṣubú.”Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì tún sọkún lórí rẹ̀.

35. Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì wá láti gba Dáfídì ní ìyànjú kí ó jẹun, nígbà tí ọjọ́ sì ń bẹ, Dáfídì sì búra wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí èmi yóò bá tọ́ ounjẹ wò, tàbí nǹkan mìíràn títí òòrùn yóò fi wọ̀!”

2 Sámúẹ́lì 3